Ìkédè Pàtàkì:
Fún Ayẹyẹ Ọdún Kẹẹdọgbọn (25th year Anniversary) ti YORUBA AMERICAN COMMUNITY (YAC ) àti Ìkójọ Owó fún Ilé Yorùbá (Yoruba House)
Ẹ kú ọjọ́ méjì meta, gbogbo ọmọ Yorùbá àti àwọn olólùfẹ́ àṣà wa.
Pẹ̀lú ayọ̀ àti ọpẹ́ si olorun, àwa omọ̀ Egbe Yoruba American Community (YAC) kéde ayẹyẹ ọdún kẹẹdọgbọn (25th year) tí a ti dá ẹgbẹ́ yìí sílẹ̀ láti máa tọ́jú, múlò, àti igbélaruge àṣà, èdè, àti ìṣe Yorùbá ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà.
Kí ni à ń pè yín sí?
Ayẹyẹ Ọdún Kẹẹdọgbọn (25th Anniversary Celebration): Ìpàdé ńlá àti ayẹyẹ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run àti láti fi ọlá fún àwọn tí wọ́n ti lààmilaaka fún ìdàgbàsókè ẹgbẹ́ wa.
Ìkójọ Owó fún Ilé Yorùbá (Yoruba House Fundraising): Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ńlá kan, a nílò láti kówó jọ fún rírà ilé tí yóò jẹ́ ibùdó, àdúgbò, àti ilé ìkẹ́kọ̀ọ́ àṣà fún gbogbo ọmọ Yorùbá àti àwọn ololufe wa.
Ẹ gbiyanju láti wá síbi ayẹyẹ wa, tí yóò waye ni gbongan , DIVINE PROVIDENCE LITHUANIAN 25335 W NINE MILE ROAD SOUTHFIELD, MICHIGAN ni deede agogo Marun , Ọjọ́ Kọ́kàndínlọ́gbọ̀n, Oṣù Kọkànlá, Ọdún 2025
Yoruba American Community (YAC), Níṣọkàn fún Ìgbélárugẹ asa, ede, iwa, wa.
